Genesis 45 - Listen Online
Read Genesis 45
1 NIGBANA ni Josefu kò le mu oju dá mọ́ niwaju gbogbo awọn ti o duro tì i; o si kigbe pe, Ẹ mu ki gbogbo enia ki o jade kuro lọdọ mi. Ẹnikẹni kò si duro tì i, nigbati Josefu sọ ara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀.
1 Then Joseph could not refrain himself before all them that stood by him; and he cried, Cause every man to go out from me. And there stood no man with him, while Joseph made himself known unto his brethren.
2 O si sọkun kikan: ati awọn ara Egipti ati awọn ara ile Farao gbọ́.
2 And he wept aloud: and the Egyptians and the house of Pharaoh heard.
3 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi ni Josefu; baba mi wà sibẹ̀? awọn arakunrin rẹ̀ kò si le da a lohùn; nitori ti ẹ̀ru bà wọn niwaju rẹ̀.
3 And Joseph said unto his brethren, I am Joseph; doth my father yet live? And his brethren could not answer him; for they were troubled at his presence.
4 Josefu si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Emi bẹ̀ nyin ẹ sunmọ ọdọ mi. Nwọn si sunmọ ọ. O si wi pe, Emi ni Josefu, arakunrin nyin, ti ẹnyin tà si Egipti.
4 And Joseph said unto his brethren, Come near to me, I pray you. And they came near. And he said, I am Joseph your brother, whom ye sold into Egypt.
5 Njẹ nisisiyi, ẹ máṣe binujẹ, ki ẹ má si ṣe binu si ara nyin, ti ẹnyin tà mi si ihin: nitori pe, Ọlọrun li o rán mi siwaju nyin lati gbà ẹmi là.
5 Now therefore be not grieved, nor angry with yourselves, that ye sold me hither: for God did send me before you to preserve life.
6 Lati ọdún meji yi ni ìyan ti nmú ni ilẹ: o si tun kù ọdún marun si i, ninu eyiti a ki yio ni itulẹ tabi ikorè.
6 For these two years hath the famine been in the land: and yet there are five years, in the which there shall neither be earing nor harvest.
7 Ọlọrun si rán mi siwaju nyin lati da irú-ọmọ si fun nyin lori ilẹ, ati lati fi ìgbala nla gbà ẹmi nyin là.
7 And God sent me before you to preserve you a posterity in the earth, and to save your lives by a great deliverance.
8 Njẹ nisisiyi, ki iṣe ẹnyin li o rán mi si ihin, bikoṣe Ọlọrun: o si ti fi mi ṣe baba fun Farao, ati oluwa gbogbo ile rẹ̀, ati alakoso gbogbo ilẹ Egipti.
8 So now it was not you that sent me hither, but God: and he hath made me a father to Pharaoh, and lord of all his house, and a ruler throughout all the land of Egypt.
9 Ẹ yara ki ẹ si goke tọ̀ baba mi lọ, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi ni Josefu ọmọ rẹ wipe, Ọlọrun fi mi jẹ́ oluwa gbogbo Egipti: sọkalẹ tọ̀ mi wá, má si ṣe duro.
9 Haste ye, and go up to my father, and say unto him, Thus saith thy son Joseph, God hath made me lord of all Egypt: come down unto me, tarry not:
10 Iwọ o si joko ni ilẹ Goṣeni, iwọ o si wà leti ọdọ mi, iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ, ati ọwọ-ẹran rẹ, ati ọwọ́-malu rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní.
10 And thou shalt dwell in the land of Goshen, and thou shalt be near unto me, thou, and thy children, and thy children's children, and thy flocks, and thy herds, and all that thou hast:
11 Nibẹ̀ li emi o si ma bọ́ ọ; nitori ọdún ìyan kù marun si i; ki iwọ, ati awọn ara ile rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní, ki o má ba ri ipọnju.
11 And there will I nourish thee; for yet there are five years of famine; lest thou, and thy household, and all that thou hast, come to poverty.
12 Si kiyesi i, oju nyin, ati oju Benjamini arakunrin mi ri pe, ẹnu mi li o nsọ̀rọ fun nyin.
12 And, behold, your eyes see, and the eyes of my brother Benjamin, that it is my mouth that speaketh unto you.
13 Ki ẹnyin ki o si ròhin gbogbo ogo mi ni Egipti fun baba mi, ati ti ohun gbogbo ti ẹnyin ri; ki ẹnyin ki o si yara, ki ẹ si mú baba mi sọkalẹ wá ihin.
13 And ye shall tell my father of all my glory in Egypt, and of all that ye have seen; and ye shall haste and bring down my father hither.
14 O si rọ̀mọ́ Benjamini arakunrin rẹ̀ li ọrùn, o si sọkun; Benjamini si sọkun li ọrùn rẹ̀.
14 And he fell upon his brother Benjamin's neck, and wept; and Benjamin wept upon his neck.
15 O si fi ẹnu kò gbogbo awọn arakunrin rẹ̀ li ẹnu, o si sọkun si wọn lara: lẹhin eyini li awọn arakunrin rẹ̀ bá a sọ̀rọ.
15 Moreover he kissed all his brethren, and wept upon them: and after that his brethren talked with him.
16 A si gbọ́ ìhin na ni ile Farao pe, awọn arakunrin Josefu dé: o si dùn mọ́ Farao ati awọn iranṣẹ rẹ̀.
16 And the fame thereof was heard in Pharaoh's house, saying, Joseph's brethren are come: and it pleased Pharaoh well, and his servants.
17 Farao si wi fun Josefu pe, Wi fun awọn arakunrin rẹ, Eyi ni ki ẹ ṣe; ẹ dì ẹrù lé ẹranko nyin, ki ẹ si lọ si ilẹ Kenaani;
17 And Pharaoh said unto Joseph, Say unto thy brethren, This do ye; lade your beasts, and go, get you unto the land of Canaan;
18 Ẹ si mú baba nyin, ati awọn ara ile nyin, ki ẹ si tọ̀ mi wá; emi o si fun nyin li ohun rere ilẹ Egipti, ẹnyin o si ma jẹ ọrá ilẹ yi.
18 And take your father and your households, and come unto me: and I will give you the good of the land of Egypt, and ye shall eat the fat of the land.
19 Njẹ a fun ọ li aṣẹ, eyi ni ki ẹ ṣe; ẹ mú kẹkẹ́-ẹrù lati ilẹ Egipti fun awọn ọmọ wẹrẹ nyin, ati fun awọn aya nyin, ki ẹ si mú baba nyin, ki ẹ si wá.
19 Now thou art commanded, this do ye; take you wagons out of the land of Egypt for your little ones, and for your wives, and bring your father, and come.
20 Ẹ má si ṣe aniyàn ohun-èlo; nitori ohun rere gbogbo ilẹ Egipti ti nyin ni.
20 Also regard not your stuff; for the good of all the land of Egypt is yours.
21 Awọn ọmọ Israeli si ṣe bẹ̃: Josefu si fi kẹkẹ́-ẹrù fun wọn, gẹgẹ bi aṣẹ Farao, o si fi onjẹ ọ̀na fun wọn.
21 And the children of Israel did so: and Joseph gave them wagons, according to the commandment of Pharaoh, and gave them provision for the way.
22 O fi ìparọ-aṣọ fun gbogbo wọn fun olukuluku wọn; ṣugbọn Benjamini li o fi ọdunrun owo fadaka fun, ati ìparọ-aṣọ marun.
22 To all of them he gave each man changes of raiment; but to Benjamin he gave three hundred pieces of silver, and five changes of raiment.
23 Bayi li o si ranṣẹ si baba rẹ̀; kẹtẹkẹtẹ mẹwa ti o rù ohun rere Egipti, ati abo-kẹtẹkẹtẹ mẹwa ti o rù ọkà ati àkara ati onjẹ fun baba rẹ̀ li ọ̀na.
23 And to his father he sent after this manner; ten asses laden with the good things of Egypt, and ten she asses laden with corn and bread and meat for his father by the way.
24 Bẹ̃li o rán awọn arakunrin rẹ̀ lọ, nwọn si lọ: o si wi fun wọn pe, Ẹ máṣe jà li ọ̀na.
24 So he sent his brethren away, and they departed: and he said unto them, See that ye fall not out by the way.
25 Nwọn si goke lati ilẹ Egipti lọ, nwọn si dé ọdọ Jakobu baba wọn ni ilẹ Kenaani.
25 And they went up out of Egypt, and came into the land of Canaan unto Jacob their father,
26 Nwọn si wi fun u pe, Josefu mbẹ lãye sibẹ̀, on si ni bãlẹ gbogbo ilẹ Egipti. O si rẹ̀ Jakobu dé inu nitori ti kò gbà wọn gbọ́.
26 And told him, saying, Joseph is yet alive, and he is governor over all the land of Egypt. And Jacob's heart fainted, for he believed them not.
27 Nwọn si sọ ọ̀rọ Josefu gbogbo fun u, ti o wi fun wọn: nigbati o si ri kẹkẹ́-ẹrù ti Josefu rán wá lati fi mú u lọ, ọkàn Jakobu baba wọn sọji:
27 And they told him all the words of Joseph, which he had said unto them: and when he saw the wagons which Joseph had sent to carry him, the spirit of Jacob their father revived:
28 Israeli si wipe, O tó; Josefu ọmọ mi mbẹ lãye sibẹ̀; emi o lọ ki nsi ri i ki emi ki o to kú.
28 And Israel said, It is enough; Joseph my son is yet alive: I will go and see him before I die.