Genesis 28 - Listen Online
Read Genesis 28
1 ISAAKI si pè Jakobu, o si sùre fun u, o si kìlọ fun u, o si wi fun u pe, Iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani.
1 And Isaac called Jacob, and blessed him, and charged him, and said unto him, Thou shalt not take a wife of the daughters of Canaan.
2 Dide, lọ si Padan-aramu, si ile Betueli, baba iya rẹ; ki iwọ ki o si fẹ́ aya lati ibẹ̀ wá ninu awọn ọmọbinrin Labani, arakunrin iya rẹ.
2 Arise, go to Padan-aram, to the house of Bethuel thy mother's father; and take thee a wife from thence of the daughters of Laban thy mother's brother.
3 Ki Ọlọrun Olodumare ki o gbè ọ, ki o si mu ọ bisi i, ki o si mu ọ rẹ̀ si i, ki iwọ ki o le di ọ̀pọlọpọ enia.
3 And God Almighty bless thee, and make thee fruitful, and multiply thee, that thou mayest be a multitude of people;
4 Ki o si fi ibukún Abrahamu fun ọ, fun iwọ ati fun irú-ọmọ rẹ pẹlu rẹ; ki iwọ ki o le ni ilẹ na ninu eyiti iwọ nṣe atipo, ti Ọlọrun fi fun Abrahamu.
4 And give thee the blessing of Abraham, to thee, and to thy seed with thee; that thou mayest inherit the land wherein thou art a stranger, which God gave unto Abraham.
5 Isaaki si rán Jakobu lọ: o si lọ si Padan-aramu si ọdọ Labani, ọmọ Betueli, ara Siria, arakunrin Rebeka, iya Jakobu on Esau.
5 And Isaac sent away Jacob: and he went to Padan-aram unto Laban, son of Bethuel the Syrian, the brother of Rebekah, Jacob's and Esau's mother.
6 Nigbati Esau ri pe Isaaki sure fun Jakobu ti o si rán a lọ si Padan-aramu, lati fẹ́ aya lati ibẹ̀; ati pe bi o ti sure fun u, o si kìlọ fun u wipe, iwọ kò gbọdọ fẹ́ aya ninu awọn ọmọbinrin Kenaani;
6 When Esau saw that Isaac had blessed Jacob, and sent him away to Padan-aram, to take him a wife from thence; and that as he blessed him he gave him a charge, saying, Thou shalt not take a wife of the daughters of Canaan;
7 Ati pe Jakobu gbọ́ ti baba ati ti iya rẹ̀, ti o si lọ si Padan-aramu:
7 And that Jacob obeyed his father and his mother, and was gone to Padan-aram;
8 Nigbati Esau ri pe awọn ọmọbinrin Kenaani kò wù Isaaki baba rẹ̀;
8 And Esau seeing that the daughters of Canaan pleased not Isaac his father;
9 Nigbana ni Esau tọ̀ Iṣmaeli lọ, o si fẹ́ Mahalati ọmọbinrin Iṣmaeli, ọmọ Abrahamu, arabinrin Nebajotu, kún awọn obinrin ti o ni.
9 Then went Esau unto Ishmael, and took unto the wives which he had Mahalath the daughter of Ishmael Abraham's son, the sister of Nebajoth, to be his wife.
10 Jakobu si jade kuro lati Beer-ṣeba lọ, o si lọ si ìha Harani.
10 And Jacob went out from Beer-sheba, and went toward Haran.
11 O si de ibi kan, o duro nibẹ̀ li oru na, nitori õrùn wọ̀; o si mu ninu okuta ibẹ̀ na, o fi ṣe irọri rẹ̀, o si sùn nibẹ̀ na.
11 And he lighted upon a certain place, and tarried there all night, because the sun was set; and he took of the stones of that place, and put them for his pillows, and lay down in that place to sleep.
12 O si lá alá, si kiyesi i, a gbé àkasọ kan duro lori ilẹ, ori rẹ̀ si de oke ọrun: si kiyesi i, awọn angeli Ọlọrun ngoke, nwọn si nsọkalẹ lori rẹ̀.
12 And he dreamed, and behold a ladder set up on the earth, and the top of it reached to heaven: and behold the angels of God ascending and descending on it.
13 Si kiyesi i, OLUWA duro loke rẹ̀, o si wi pe, Emi li OLUWA, Ọlọrun Abrahamu baba rẹ, ati Ọlọrun Isaaki; ilẹ ti iwọ dubulẹ le nì, iwọ li emi o fi fun, ati fun irú-ọmọ rẹ.
13 And, behold, the LORD stood above it, and said, I am the LORD God of Abraham thy father, and the God of Isaac: the land whereon thou liest, to thee will I give it, and to thy seed;
14 Irú-ọmọ rẹ yio si ri bi erupẹ̀ ilẹ, iwọ o si tàn kalẹ si ìha ìwọ-õrùn, ati si ìha ìla-õrùn, ati si ìha ariwa, ati si ìha gusù: ninu rẹ, ati ninu irú-ọmọ rẹ li a o bukún fun gbogbo ibatan aiye.
14 And thy seed shall be as the dust of the earth, and thou shalt spread abroad to the west, and to the east, and to the north, and to the south: and in thee and in thy seed shall all the families of the earth be blessed.
15 Si kiyesi i, emi wà pẹlu rẹ, emi o sì pa ọ mọ́ ni ibi gbogbo ti iwọ nlọ, emi o si tun mu ọ bọ̀wá si ilẹ yi; nitori emi ki yio kọ̀ ọ silẹ, titi emi o fi ṣe eyiti mo wi fun ọ tan.
15 And, behold, I am with thee, and will keep thee in all places whither thou goest, and will bring thee again into this land; for I will not leave thee, until I have done that which I have spoken to thee of.
16 Jakobu si jí li oju-orun rẹ̀, o si wipe, OLUWA mbẹ nihinyi nitõtọ; emi kò si mọ̀.
16 And Jacob awaked out of his sleep, and he said, Surely the LORD is in this place; and I knew it not.
17 Ẹrù si bà a, o si wipe, Ihinyi ti li ẹ̀ru tó! eyi ki iṣe ibi omiran, bikoṣe ile Ọlọrun, eyi si li ẹnubode ọrun.
17 And he was afraid, and said, How dreadful is this place! this is none other but the house of God, and this is the gate of heaven.
18 Jakobu si dide ni kutukutu owurọ̀, o si mu okuta ti o fi ṣe irọri rẹ̀, o si fi lelẹ fun ọwọ̀n, o si ta oróro si ori rẹ̀.
18 And Jacob rose up early in the morning, and took the stone that he had put for his pillows, and set it up for a pillar, and poured oil upon the top of it.
19 O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Beteli: ṣugbọn Lusi li orukọ ilu na ri.
19 And he called the name of that place Bethel: but the name of that city was called Luz at the first.
20 Jakobu si jẹ́ ẹjẹ́ wipe, Bi Ọlọrun ba pẹlu mi, ti o si pa mi mọ́ li ọ̀na yi ti emi ntọ̀, ti o si fun mi li ohun jijẹ, ati aṣọ bibora,
20 And Jacob vowed a vow, saying, If God will be with me, and will keep me in this way that I go, and will give me bread to eat, and raiment to put on,
21 Ti mo si pada wá si ile baba mi li alafia; njẹ OLUWA ni yio ma ṣe Ọlọrun mi.
21 So that I come again to my father's house in peace; then shall the LORD be my God:
22 Okuta yi, ti mo fi lelẹ ṣe ọwọ̀n ni yio si ṣe ile Ọlọrun: ati ninu ohun gbogbo ti iwọ o fi fun mi, emi o si fi idamẹwa rẹ̀ fun ọ.
22 And this stone, which I have set for a pillar, shall be God's house: and of all that thou shalt give me I will surely give the tenth unto thee.