Ezekiel 42 - Listen Online
Read Ezekiel 42
1 O si mu mi wá si agbala ode, li ọ̀na apa ariwa: o si mu mi wá si yará ti o kọju si ibi ti a yà sọtọ̀, ti o si kọju si ile lọna ariwa.
1 Then he brought me forth into the utter court, the way toward the north: and he brought me into the chamber that was over against the separate place, and which was before the building toward the north.
2 Niwaju, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn ni ilẹkun ariwa, ati ibú rẹ̀ ãdọta igbọnwọ.
2 Before the length of an hundred cubits was the north door, and the breadth was fifty cubits.
3 Niwaju, ogún igbọnwọ ti o wà fun agbalá ti inu, ati niwaju itẹle ti o wà fun agbalá ti ode; ibujoko oke ti o kọju si ibujoko-oke wà ni orule mẹta.
3 Over against the twenty cubits which were for the inner court, and over against the pavement which was for the utter court, was gallery against gallery in three stories.
4 Ati niwaju awọn yará ni irìn igbọnwọ mẹwa ni ibú ninu, ọ̀na igbọnwọ kan; ilẹkùn wọn si wà nihà ariwa.
4 And before the chambers was a walk of ten cubits breadth inward, a way of one cubit; and their doors toward the north.
5 Ati awọn yará oke kuru jù; nitori ibujoko ti awọn yará isalẹ ati yará ãrin yọ siwaju wọnyi ti ile.
5 Now the upper chambers were shorter: for the galleries were higher than these, than the lower, and than the middlemost of the building.
6 Nitori nwọn jẹ olorule mẹta, ṣugbọn nwọn kò ni ọwọ̀n bi ọwọ̀n agbalá: nitorina a fasẹhin kuro ninu yará isalẹ ati kuro ninu yará ãrin lati ilẹ wá.
6 For they were in three stories, but had not pillars as the pillars of the courts: therefore the building was straitened more than the lowest and the middlemost from the ground.
7 Ati ogiri ti o wà lode ti o kọju si yará, li apa agbala ode niwaju yará, gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ.
7 And the wall that was without over against the chambers, toward the utter court on the forepart of the chambers, the length thereof was fifty cubits.
8 Nitori gigùn awọn yará ti o wà lode jẹ ãdọta igbọnwọ: si wò o, niwaju tempili o jẹ ọgọrun igbọnwọ.
8 For the length of the chambers that were in the utter court was fifty cubits: and, lo, before the temple were an hundred cubits.
9 Ati lati isalẹ yará wọnyi ni iwọle li ọ̀na ila-õrun wà, bi a ti nlọ sinu wọn lati agbala ode wá.
9 And from under these chambers was the entry on the east side, as one goeth into them from the utter court.
10 Ni ibú ogiri agbala, li ọ̀na ila-õrun niwaju ibiti a yà sọtọ̀, ati niwaju ile na, ni awọn yará na wà.
10 The chambers were in the thickness of the wall of the court toward the east, over against the separate place, and over against the building.
11 Ati ọ̀na iwaju wọn ti gẹgẹ bi iri awọn yará ti o wà li ọ̀na ariwa, bi nwọn ti gùn mọ, bẹ̃ ni nwọn gbòro mọ: ati gbogbo ijade wọn si dabi iṣe wọn, ati bi ilẹkùn wọn.
11 And the way before them was like the appearance of the chambers which were toward the north, as long as they, and as broad as they: and all their goings out were both according to their fashions, and according to their doors.
12 Bẹ̃ gẹgẹ ni yará ti on ti ilẹkùn wọn li ọ̀na gusu, ilẹkùn kan wà lori ọ̀na, li ọ̀na gbọran niwaju ogiri li ọ̀na ila-õrun bi a ti nwọ̀ inu wọn.
12 And according to the doors of the chambers that were toward the south was a door in the head of the way, even the way directly before the wall toward the east, as one entereth into them.
13 O si wi fun mi pe, Awọn yará ariwa ati awọn yará gusu, ti o wà niwaju ibiti a yà sọtọ̀, awọn ni yará mimọ́, nibiti awọn alufa ti nsunmọ Oluwa yio ma jẹ ohun mimọ́ julọ: nibẹ̀ ni nwọn o ma gbe ohun mimọ́ julọ kà, ati ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; nitori ibẹ̀ jẹ mimọ́.
13 Then said he unto me, The north chambers and the south chambers, which are before the separate place, they be holy chambers, where the priests that approach unto the LORD shall eat the most holy things: there shall they lay the most holy things, and the meat offering, and the sin offering, and the trespass offering; for the place is holy.
14 Nigbati awọn alufa ba wọ̀ ibẹ̀, nwọn kì yio si kuro ni ibi mimọ́ si agbala ode, ṣugbọn nibẹ nibiti nwọn gbe nṣiṣẹ ni nwọn o fi ẹwù wọn si; nitori nwọn jẹ mimọ́; nwọn o si wọ̀ ẹwù miran, nwọn o si sunmọ nkan wọnni ti o jẹ́ ti enia.
14 When the priests enter therein, then shall they not go out of the holy place into the utter court, but there they shall lay their garments wherein they minister; for they are holy; and shall put on other garments, and shall approach to those things which are for the people.
15 Nigbati o si ti wọ̀n ile ti inu tan, o mu mi wá sihà ilẹkùn ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si wọ̀n yika.
15 Now when he had made an end of measuring the inner house, he brought me forth toward the gate whose prospect is toward the east, and measured it round about.
16 O fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ila-õrun, ẹ̃dẹgbẹta ije, nipa ije iwọ̀nlẹ yika.
16 He measured the east side with the measuring reed, five hundred reeds, with the measuring reed round about.
17 O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa ariwa, ẹ̃dẹgbẹta ije yika.
17 He measured the north side, five hundred reeds, with the measuring reed round about.
18 O si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ti apa gusu, ẹ̃dẹgbẹta ije.
18 He measured the south side, five hundred reeds, with the measuring reed.
19 O yipadà si ọ̀na iwọ-õrun, o si fi ije iwọ̀nlẹ wọ̀n ọ, ẹ̃dẹgbẹta ije.
19 He turned about to the west side, and measured five hundred reeds with the measuring reed.
20 O wọ̀n ọ nihà mẹrẹrin: o ni ogiri kan yi i ka, ẹ̃dẹgbẹta ije ni gigùn, ati ẹ̃dẹgbẹta ni ibú, lati pàla lãrin ibi mimọ́ ati ibi aimọ́.
20 He measured it by the four sides: it had a wall round about, five hundred reeds long, and five hundred broad, to make a separation between the sanctuary and the profane place.