Ezekiel 2 - Listen Online
Read Ezekiel 2
1 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, duro li ẹsẹ rẹ, emi o si ba ọ sọ̀rọ.
1 And he said unto me, Son of man, stand upon thy feet, and I will speak unto thee.
2 Ẹmi si wọ inu mi, nigbati o ba mi sọ̀rọ o si gbe mi duro li ẹsẹ mi, mo si gbọ́ ẹniti o ba mi sọrọ.
2 And the spirit entered into me when he spake unto me, and set me upon my feet, that I heard him that spake unto me.
3 O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, emi ran ọ si awọn ọmọ Israeli, si ọlọtẹ̀ orilẹ-ède, ti o ti ṣọtẹ si mi: awọn ati baba wọn ti ṣẹ̀ si mi titi di oni oloni.
3 And he said unto me, Son of man, I send thee to the children of Israel, to a rebellious nation that hath rebelled against me: they and their fathers have transgressed against me, even unto this very day.
4 Nitori ọmọ alafojudi ati ọlọkàn lile ni nwọn, Emi rán ọ si wọn; iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi.
4 For they are impudent children and stiffhearted. I do send thee unto them; and thou shalt say unto them, Thus saith the Lord GOD.
5 Ati awọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi nwọn o kọ̀, (nitori ọlọtẹ̀ ile ni nwọn) sibẹ nwọn o mọ̀ pe woli kan ti wà larin wọn.
5 And they, whether they will hear, or whether they will forbear, (for they are a rebellious house,) yet shall know that there hath been a prophet among them.
6 Ati iwọ, ọmọ enia, máṣe bẹ̀ru wọn, bẹ̃ni ki o máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bi ẹgun ọgàn ati oṣuṣu tilẹ pẹlu rẹ, ti iwọ si gbe ãrin akẽkẽ: máṣe bẹ̀ru ọ̀rọ wọn, bẹ̃ni ki o máṣe foya wiwò wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ọlọtẹ̀ ile.
6 And thou, son of man, be not afraid of them, neither be afraid of their words, though briers and thorns be with thee, and thou dost dwell among scorpions: be not afraid of their words, nor be dismayed at their looks, though they be a rebellious house.
7 Iwọ o si sọ ọ̀rọ mi fun wọn, bi nwọn o gbọ́, tabi bi wọn o kọ̀: nitoriti nwọn jẹ ọlọtẹ̀.
7 And thou shalt speak my words unto them, whether they will hear, or whether they will forbear: for they are most rebellious.
8 Ṣugbọn iwọ, ọmọ enia, gbọ́ ohun ti mo sọ fun ọ; Iwọ máṣe jẹ ọlọtẹ̀ bi ọlọtẹ̀ ile nì: ya ẹ̀nu rẹ, ki o si jẹ ohun ti mo fi fun ọ.
8 But thou, son of man, hear what I say unto thee; Be not thou rebellious like that rebellious house: open thy mouth, and eat that I give thee.
9 Nigbati mo wò, si kiye si i, a ran ọwọ́ kan si mi; si kiye si i, iká-iwé kan wà ninu rẹ̀.
9 And when I looked, behold, an hand was sent unto me; and, lo, a roll of a book was therein;
10 O si tẹ́ ẹ siwaju mi, a si kọ ọ ninu ati lode: a si kọ ohùn-reré-ẹkun, ati ọ̀fọ, ati egbé.
10 And he spread it before me; and it was written within and without: and there was written therein lamentations, and mourning, and woe.