Deuteronomy 27 - Listen Online
Read Deuteronomy 27
1 MOSE pẹlu awọn àgba Israeli si paṣẹ fun awọn enia na wipe, Ẹ ma pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni.
1 And Moses with the elders of Israel commanded the people, saying, Keep all the commandments which I command you this day.
2 Yio si ṣe li ọjọ́ ti ẹnyin ba gòke Jordani lọ si ilẹ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ki iwọ ki o si kó okuta nla jọ, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn.
2 And it shall be on the day when ye shall pass over Jordan unto the land which the LORD thy God giveth thee, that thou shalt set thee up great stones, and plaister them with plaister:
3 Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara wọn, nigbati iwọ ba rekọja; ki iwọ ki o le wọ̀ inu ilẹ na lọ ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ, ti ṣe ileri fun ọ.
3 And thou shalt write upon them all the words of this law, when thou art passed over, that thou mayest go in unto the land which the LORD thy God giveth thee, a land that floweth with milk and honey; as the LORD God of thy fathers hath promised thee.
4 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani tán, ẹnyin o kó okuta wọnyi jọ, ti mo palaṣẹ fun nyin li oni, li òke Ebali, ki iwọ ki o si fi ẹfun rẹ́ wọn.
4 Therefore it shall be when ye be gone over Jordan, that ye shall set up these stones, which I command you this day, in mount Ebal, and thou shalt plaister them with plaister.
5 Nibẹ̀ ni ki iwọ ki o si mọ pẹpẹ kan fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pẹpẹ okuta kan: iwọ kò gbọdọ fi ohun-èlo irin kàn wọn.
5 And there shalt thou build an altar unto the LORD thy God, an altar of stones: thou shalt not lift up any iron tool upon them.
6 Okuta aigbẹ́ ni ki iwọ ki o fi mọ pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun lori rẹ̀ si OLUWA Ọlọrun rẹ:
6 Thou shalt build the altar of the LORD thy God of whole stones: and thou shalt offer burnt offerings thereon unto the LORD thy God:
7 Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ alafia, ki iwọ ki o si jẹun nibẹ̀; ki iwọ ki o ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ.
7 And thou shalt offer peace offerings, and shalt eat there, and rejoice before the LORD thy God.
8 Ki iwọ ki o si kọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi sara okuta wọnyi, ki o hàn gbangba.
8 And thou shalt write upon the stones all the words of this law very plainly.
9 Mose ati awọn alufa awọn ọmọ Lefi si sọ fun gbogbo Israeli pe, Israeli, dakẹ, ki o si gbọ́; li oni ni iwọ di enia OLUWA Ọlọrun rẹ.
9 And Moses and the priests the Levites spake unto all Israel, saying, Take heed, and hearken, O Israel; this day thou art become the people of the LORD thy God.
10 Nitorina ki iwọ ki o gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, ki o si ma ṣe aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni.
10 Thou shalt therefore obey the voice of the LORD thy God, and do his commandments and his statutes, which I command thee this day.
11 Mose si paṣẹ fun awọn enia na li ọjọ́ na, wipe,
11 And Moses charged the people the same day, saying,
12 Awọn wọnyi ni ki o duro lori òke Gerisimu, lati ma sure fun awọn enia na, nigbati ẹnyin ba gòke Jordani; Simeoni, ati Lefi, ati Juda, ati Issakari, ati Josefu, ati Benjamini:
12 These shall stand upon mount Gerizim to bless the people, when ye are come over Jordan; Simeon, and Levi, and Judah, and Issachar, and Joseph, and Benjamin:
13 Awọn wọnyi ni yio si duro lori òke Ebali lati gegún; Reubeni, Gadi, ati Aṣeri, ati Sebuluni, Dani, ati Naftali.
13 And these shall stand upon mount Ebal to curse; Reuben, Gad, and Asher, and Zebulun, Dan, and Naphtali.
14 Awọn ọmọ Lefi yio si dahùn, nwọn o si wi fun gbogbo awọn ọkunrin Israeli li ohùn rara pe,
14 And the Levites shall speak, and say unto all the men of Israel with a loud voice,
15 Egún ni fun ọkunrin na ti o yá ere gbigbẹ́ tabi didà, irira si OLUWA, iṣẹ ọwọ́ oniṣọnà, ti o si gbé e kalẹ ni ìkọ̀kọ̀. Gbogbo enia yio si dahùn wipe, Amin.
15 Cursed be the man that maketh any graven or molten image, an abomination unto the LORD, the work of the hands of the craftsman, and putteth it in a secret place. And all the people shall answer and say, Amen.
16 Egún ni fun ẹniti kò fi baba rẹ̀ tabi iya rẹ̀ pè. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
16 Cursed be he that setteth light by his father or his mother. And all the people shall say, Amen.
17 Egún ni fun ẹniti o ṣí àla ẹnikeji rẹ̀ kuro. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
17 Cursed be he that removeth his neighbour's landmark. And all the people shall say, Amen.
18 Egún ni fun ẹniti o ṣì afọju li ọ̀na. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
18 Cursed be he that maketh the blind to wander out of the way. And all the people shall say, Amen.
19 Egún ni fun ẹniti o nyi idajọ alejò po, ati ti alainibaba, ati ti opó. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
19 Cursed be he that perverteth the judgment of the stranger, fatherless, and widow. And all the people shall say, Amen.
20 Egún ni fun ẹniti o bá aya baba rẹ̀ dàpọ̀: nitoriti o tú aṣọ baba rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
20 Cursed be he that lieth with his father's wife; because he uncovereth his father's skirt. And all the people shall say, Amen.
21 Egún ni fun ẹniti o bá ẹranko dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
21 Cursed be he that lieth with any manner of beast. And all the people shall say, Amen.
22 Egún ni fun ẹniti o bá arabinrin rẹ̀ dàpọ, ti iṣe ọmọbinrin baba rẹ̀, tabi ọmọbinrin iya rẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
22 Cursed be he that lieth with his sister, the daughter of his father, or the daughter of his mother. And all the people shall say, Amen.
23 Egún ni fun ẹniti o bá iya-aya rẹ̀ dàpọ. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
23 Cursed be he that lieth with his mother in law. And all the people shall say, Amen.
24 Egún ni fun ẹniti o lù ẹnikeji rẹ̀ ni ìkọkọ. Gbogbo enia ni yio si wipe, Amin.
24 Cursed be he that smiteth his neighbour secretly. And all the people shall say, Amen.
25 Egún ni fun ẹniti o gbà ọrẹ lati pa alaiṣẹ̀. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
25 Cursed be he that taketh reward to slay an innocent person. And all the people shall say, Amen.
26 Egún ni fun ẹniti kò duro si gbogbo ọ̀rọ ofin yi lati ṣe wọn. Gbogbo enia yio si wipe, Amin.
26 Cursed be he that confirmeth not all the words of this law to do them. And all the people shall say, Amen.