Acts 6 - Listen Online
Read Acts 6
1 NJẸ li ọjọ wọnni, nigbati iye awọn ọmọ-ẹhin npọ̀ si i, ikùn-sinu wà ninu awọn Hellene si awọn Heberu, nitoriti a nṣe igbagbé awọn opó wọn ni ipinfunni ojojumọ́.
1 And in those days, when the number of the disciples was multiplied, there arose a murmuring of the Grecians against the Hebrews, because their widows were neglected in the daily ministration.
2 Awọn mejila si pè ọpọlọpọ awọn ọmọ-ẹhin jọ̀ sọdọ, nwọn wipe, Kò yẹ ti awa iba fi ọ̀rọ Ọlọrun silẹ, ki a si mã ṣe iranṣẹ tabili.
2 Then the twelve called the multitude of the disciples unto them, and said, It is not reason that we should leave the word of God, and serve tables.
3 Nitorina, ará, ẹ wo ọkunrin meje ninu nyin, olorukọ rere, ẹniti o kún fun Ẹmí Mimọ́ ati fun ọgbọ́n, ẹniti awa iba yàn si iṣẹ yi.
3 Wherefore, brethren, look ye out among you seven men of honest report, full of the Holy Ghost and wisdom, whom we may appoint over this business.
4 Ṣugbọn awa o duro ṣinṣin ninu adura igbà, ati ninu iṣẹ iranṣẹ ọ̀rọ na.
4 But we will give ourselves continually to prayer, and to the ministry of the word.
5 Ọ̀rọ na si tọ́ loju gbogbo ijọ: nwọn si yàn Stefanu, ọkunrin ti o kún fun igbagbọ́ ati fun Ẹmí Mimọ́, ati Filippi ati Prokoru, ati Nikanoru, ati Timoni, ati Parmena, ati Nikola alawọṣe Ju ara Antioku:
5 And the saying pleased the whole multitude: and they chose Stephen, a man full of faith and of the Holy Ghost, and Philip, and Prochorus, and Nicanor, and Timon, and Parmenas, and Nicolas a proselyte of Antioch:
6 Ẹniti nwọn mu duro niwaju awọn aposteli: nigbati nwọn si gbadura, nwọn fi ọwọ́ le wọn.
6 Whom they set before the apostles: and when they had prayed, they laid their hands on them.
7 Ọ̀rọ Ọlọrun si gbilẹ; iye awọn ọmọ-ẹhin si pọ̀ si i gidigidi ni Jerusalemu; ọ̀pọ ninu ẹgbẹ awọn alufa si fetisi ti igbagbọ́ na.
7 And the word of God increased; and the number of the disciples multiplied in Jerusalem greatly; and a great company of the priests were obedient to the faith.
8 Ati Stefanu, ti o kún fun ore-ọfẹ ati agbara, o ṣe iṣẹ iyanu, ati iṣẹ ami nla lãrin awọn enia.
8 And Stephen, full of faith and power, did great wonders and miracles among the people.
9 Ṣugbọn awọn kan dide ninu awọn ti sinagogu, ti a npè ni ti awọn Libertine, ati ti ara Kirene, ati ti ara Aleksandria, ati ninu awọn ara Kilikia, ati ti Asia nwọn mba Stefanu jiyàn.
9 Then there arose certain of the synagogue, which is called the synagogue of the Libertines, and Cyrenians, and Alexandrians, and of them of Cilicia and of Asia, disputing with Stephen.
10 Nwọn kò si le kò ọgbọ́n ati ẹmí ti o fi nsọrọ loju.
10 And they were not able to resist the wisdom and the spirit by which he spake.
11 Nigbana ni nwọn bẹ̀ abẹtẹlẹ awọn ọkunrin, ti nwọn nwipe, Awa gbọ́ ọkunrin yi nsọ ọrọ-odi si Mose ati si Ọlọrun.
11 Then they suborned men, which said, We have heard him speak blasphemous words against Moses, and against God.
12 Nwọn si rú awọn enia soke, ati awọn àgbagba, ati awọn akọwe, nwọn dide si i, nwọn gbá a mu, nwọn mu u wá si ajọ igbimọ.
12 And they stirred up the people, and the elders, and the scribes, and came upon him, and caught him, and brought him to the council,
13 Nwọn si mu awọn ẹlẹri eke wá, ti nwọn wipe, ọkunrin yi kò simi lati sọ ọ̀rọ-òdi si ibi mimọ́ yi, ati si ofin:
13 And set up false witnesses, which said, This man ceaseth not to speak blasphemous words against this holy place, and the law:
14 Nitori awa gbọ́ o wipe, Jesu ti Nasareti yi yio fọ́ ibi yi, yio si pa iṣe ti Mose fifun wa dà.
14 For we have heard him say, that this Jesus of Nazareth shall destroy this place, and shall change the customs which Moses delivered us.
15 Ati gbogbo awọn ti o si joko ni ajọ igbimọ tẹjumọ́ ọ, nwọn nwò oju rẹ̀ bi ẹnipe oju angẹli.
15 And all that sat in the council, looking stedfastly on him, saw his face as it had been the face of an angel.