Acts 10 - Listen Online
Read Acts 10
1 ỌKUNRIN kan si wà ni Kesarea ti a npè ni Korneliu, balogun ọrún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ti a npè ni ti Itali,
1 There was a certain man in Caesarea called Cornelius, a centurion of the band called the Italian band,
2 Olufọkansìn, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹniti o nṣe itọrẹ-ãnu pipọ fun awọn enia, ti o si ngbadura sọdọ Ọlọrun nigbagbogbo.
2 A devout man, and one that feared God with all his house, which gave much alms to the people, and prayed to God alway.
3 Niwọn wakati kẹsan ọjọ, o ri ninu iran kedere angẹli Ọlọrun kan wọle tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Korneliu.
3 He saw in a vision evidently about the ninth hour of the day an angel of God coming in to him, and saying unto him, Cornelius.
4 Nigbati o si tẹjumọ́ ọ, ti ẹ̀ru si ba a, o ni, Kini, Oluwa? O si wi fun u pe, Adura rẹ ati ọrẹ-ãnu rẹ ti goke lọ iwaju Ọlọrun fun iranti.
4 And when he looked on him, he was afraid, and said, What is it, Lord? And he said unto him, Thy prayers and thine alms are come up for a memorial before God.
5 Si rán enia nisisiyi lọ si Joppa, ki nwọn si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru:
5 And now send men to Joppa, and call for one Simon, whose surname is Peter:
6 O wọ̀ si ile ẹnikan Simoni alawọ, ti ile rẹ̀ wà leti okun: on ni yio sọ fun ọ bi iwọ o ti ṣe.
6 He lodgeth with one Simon a tanner, whose house is by the sea side: he shall tell thee what thou oughtest to do.
7 Nigbati angẹli na ti o ba Korneliu sọ̀rọ si fi i silẹ lọ, o pè meji ninu awọn iranṣẹ ile rẹ̀, ati ọmọ-ogun olufọkànsin kan, ninu awọn ti ima duro tì i nigbagbogbo;
7 And when the angel which spake unto Cornelius was departed, he called two of his household servants, and a devout soldier of them that waited on him continually;
8 Nigbati o si ti rohin ohun gbogbo fun wọn, o rán wọn lọ si Joppa.
8 And when he had declared all these things unto them, he sent them to Joppa.
9 Ni ijọ keji bi nwọn ti nlọ li ọ̀na àjo wọn, ti nwọn si sunmọ ilu na, Peteru gùn oke ile lọ igbadura niwọn wakati kẹfa ọjọ:
9 On the morrow, as they went on their journey, and drew nigh unto the city, Peter went up upon the housetop to pray about the sixth hour:
10 Ebi si pa a gidigidi, on iba si jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn npèse, o bọ si ojuran,
10 And he became very hungry, and would have eaten: but while they made ready, he fell into a trance,
11 O si ri ọrun ṣí, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin, sọkalẹ si ilẹ.
11 And saw heaven opened, and a certain vessel descending unto him, as it had been a great sheet knit at the four corners, and let down to the earth:
12 Ninu rẹ̀ li olorijorí ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin wà, ati ohun ti nrakò li aiye ati ẹiyẹ oju ọrun.
12 Wherein were all manner of fourfooted beasts of the earth, and wild beasts, and creeping things, and fowls of the air.
13 Ohùn kan si fọ̀ si i pe, Dide, Peteru; mã pa ki o si mã jẹ.
13 And there came a voice to him, Rise, Peter; kill, and eat.
14 Ṣugbọn Peteru dahùn pe, Agbẹdọ, Oluwa; nitori emi kò jẹ ohun èwọ ati alaimọ́ kan ri.
14 But Peter said, Not so, Lord; for I have never eaten any thing that is common or unclean.
15 Ohùn kan si tún fọ̀ si i lẹkeji pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ mọ́.
15 And the voice spake unto him again the second time, What God hath cleansed, that call not thou common.
16 Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: lojukanna a si gbé ohun elo na pada lọ soke ọrun.
16 This was done thrice: and the vessel was received up again into heaven.
17 Bi o si ti ngọ́ Peteru ninu ara rẹ̀ bi a ba ti mọ̀ iran ti on ri yi si, si wo o, awọn ọkunrin ti a rán ti ọdọ Korneliu wá de, nwọn mbère ile Simoni, nwọn duro li ẹnu-ọ̀na,
17 Now while Peter doubted in himself what this vision which he had seen should mean, behold, the men which were sent from Cornelius had made inquiry for Simon's house, and stood before the gate,
18 Nwọn nahùn bère bi Simoni ti a npè ni Peteru, wọ̀ nibẹ.
18 And called, and asked whether Simon, which was surnamed Peter, were lodged there.
19 Bi Peteru si ti nronu iran na, Ẹmí wi fun u pe, Wo o, awọn ọkunrin mẹta nwá ọ.
19 While Peter thought on the vision, the Spirit said unto him, Behold, three men seek thee.
20 Njẹ dide, sọkalẹ ki o si ba wọn lọ, máṣe kọminu ohunkohun: nitori emi li o rán wọn.
20 Arise therefore, and get thee down, and go with them, doubting nothing: for I have sent them.
21 Nigbana ni Peteru sọkalẹ tọ̀ awọn ọkunrin ti a rán si i lati ọdọ Korneliu wá; o ni, Wo o, emi li ẹniti ẹnyin nwá: ere idi rẹ̀ ti ẹ fi wá?
21 Then Peter went down to the men which were sent unto him from Cornelius; and said, Behold, I am he whom ye seek: what is the cause wherefore ye are come?
22 Nwọn si wipe, Korneliu balogun ọrún, ọkunrin olõtọ, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si ni orukọ rere lọdọ gbogbo orilẹ-ede awọn Ju, on li a ti ọdọ Ọlọrun kọ́ nipasẹ angẹli mimọ́, lati ranṣẹ pè ọ wá si ile rẹ̀ ati lati gbọ́ ọ̀rọ li, ẹnu rẹ.
22 And they said, Cornelius the centurion, a just man, and one that feareth God, and of good report among all the nation of the Jews, was warned from God by an holy angel to send for thee into his house, and to hear words of thee.
23 Nigbana li o pè wọn wọle, o si fi wọn wọ̀. Nijọ keji o si dide, o ba wọn lọ, ninu awọn arakunrin ni Joppa si ba a lọ.
23 Then called he them in, and lodged them. And on the morrow Peter went away with them, and certain brethren from Joppa accompanied him.
24 Nijọ keji nwọn si wọ̀ Kesarea. Korneliu si ti nreti wọn, o si ti pè awọn ibatan ati awọn ọrẹ́ rẹ̀ timọtimọ jọ.
24 And the morrow after they entered into Caesarea. And Cornelius waited for them, and had called together his kinsmen and near friends.
25 O si ṣe bi Peteru ti nwọle, Korneliu pade rẹ̀, o wolẹ li ẹsẹ rẹ̀, o si foribalẹ fun u.
25 And as Peter was coming in, Cornelius met him, and fell down at his feet, and worshipped him.
26 Ṣugbọn Peteru gbé e dide, o ni, Dide; enia li emi tikarami pẹlu.
26 But Peter took him up, saying, Stand up; I myself also am a man.
27 Bi o si ti mba a sọ̀rọ, o wọle, o si bá awọn enia pipọ ti nwọn pejọ.
27 And as he talked with him, he went in, and found many that were come together.
28 O si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ bi o ti jẹ ẽwọ̀ fun ẹniti iṣe Ju, lati ba ẹniti iṣe ara ilẹ miran kẹgbẹ, tabi lati tọ̀ ọ wá; ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mi pe, ki emi ki o máṣe pè ẹnikẹni li ẽwọ̀ tabi alaimọ́.
28 And he said unto them, Ye know how that it is an unlawful thing for a man that is a Jew to keep company, or come unto one of another nation; but God hath shewed me that I should not call any man common or unclean.
29 Nitorina ni mo si ṣe wá li aijiyàn, bi a ti ranṣẹ pè mi: njẹ mo bère, nitori kili ẹnyin ṣe ranṣẹ pè mi?
29 Therefore came I unto you without gainsaying, as soon as I was sent for: I ask therefore for what intent ye have sent for me?
30 Korneliu si dahùn pe, Ni ijẹrin, mo nṣe adura wakati kẹsan ọjọ ni ile mi titi di akoko yi, si wo o, ọkunrin kan alaṣọ àla duro niwaju mi.
30 And Cornelius said, Four days ago I was fasting until this hour; and at the ninth hour I prayed in my house, and, behold, a man stood before me in bright clothing,
31 O si wipe, Korneliu, a gbọ́ adura rẹ, ọrẹ-ãnu rẹ si wà ni iranti niwaju Ọlọrun.
31 And said, Cornelius, thy prayer is heard, and thine alms are had in remembrance in the sight of God.
32 Njẹ ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru; o wọ̀ ni ile Simoni alawọ leti okun: nigbati o ba de, yio sọ̀rọ fun ọ.
32 Send therefore to Joppa, and call hither Simon, whose surname is Peter; he is lodged in the house of one Simon a tanner by the sea side: who, when he cometh, shall speak unto thee.
33 Nitorina ni mo si ti ranṣẹ si ọ lojukanna, iwọ si ṣeun ti o fi wá. Gbogbo wa pé niwaju Ọlọrun nisisiyi, lati gbọ́ ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun ọ lati ọdọ Ọlọrun wá.
33 Immediately therefore I sent to thee; and thou hast well done that thou art come. Now therefore are we all here present before God, to hear all things that are commanded thee of God.
34 Peteru si yà ẹnu rẹ̀, o si wipe, Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun kì iṣe ojuṣaju enia:
34 Then Peter opened his mouth, and said, Of a truth I perceive that God is no respecter of persons:
35 Ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ède, ẹniti o ba bẹ̀ru rẹ̀, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀.
35 But in every nation he that feareth him, and worketh righteousness, is accepted with him.
36 Ọ̀rọ ti Ọlọrun rán si awọn ọmọ Israeli, nigbati o wasu alafia nipa Jesu Kristi (on li Oluwa ohun gbogbo),
36 The word which God sent unto the children of Israel, preaching peace by Jesus Christ: (he is Lord of all:)
37 Ẹnyin na mọ̀ ọ̀rọ na ti a kede rẹ̀ yiká gbogbo Judea, ti a bẹ̀rẹ si lati Galili wá, lẹhin baptismu ti Johanu wasu rẹ̀;
37 That word, I say, ye know, which was published throughout all Judaea, and began from Galilee, after the baptism which John preached;
38 Ani Jesu ti Nasareti, bi Ọlọrun ti dà Ẹmi Mimọ́ ati agbara le e lori: ẹniti o nkiri ṣe ore, nṣe didá ara gbogbo awọn ti Èṣu si npọn loju; nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.
38 How God anointed Jesus of Nazareth with the Holy Ghost and with power: who went about doing good, and healing all that were oppressed of the devil; for God was with him.
39 Awa si li ẹlẹri gbogbo ohun ti o ṣe, ni ilẹ awọn Ju, ati ni Jerusalemu; ẹniti nwọn pa, ti nwọn si fi gbékọ sori igi:
39 And we are witnesses of all things which he did both in the land of the Jews, and in Jerusalem; whom they slew and hanged on a tree:
40 On li Ọlọrun jinde ni ijọ kẹta, o si fi i hàn gbangba:
40 Him God raised up the third day, and shewed him openly;
41 Kì iṣe fun gbogbo enia, bikoṣe fun awọn ẹlẹri ti a ti ọwọ Ọlọrun yàn tẹlẹ, fun awa, ti a ba a jẹ, ti a si ba a mu lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú.
41 Not to all the people, but unto witnesses chosen before of God, even to us, who did eat and drink with him after he rose from the dead.
42 O si paṣẹ fun wa lati wasu fun awọn enia, ati lati jẹri pe, on li a ti ọwọ Ọlọrun yàn ṣe Onidajọ ãye on okú.
42 And he commanded us to preach unto the people, and to testify that it is he which was ordained of God to be the Judge of quick and dead.
43 On ni gbogbo awọn woli jẹri si pe, nipa orukọ rẹ̀ li ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ, yio ri imukuro ẹ̀ṣẹ gbà.
43 To him give all the prophets witness, that through his name whosoever believeth in him shall receive remission of sins.
44 Bi Peteru si ti nsọ ọ̀rọ wọnyi li ẹnu, Ẹmí Mimọ́ bà le gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na.
44 While Peter yet spake these words, the Holy Ghost fell on all them which heard the word.
45 Ẹnu si yà awọn onigbagbọ ti ìkọlà, iye awọn ti o ba Peteru wá, nitoriti a tu ẹbùn Ẹmi Mimọ́ sori awọn Keferi pẹlu.
45 And they of the circumcision which believed were astonished, as many as came with Peter, because that on the Gentiles also was poured out the gift of the Holy Ghost.
46 Nitori nwọn gbọ́, nwọn nfọ onirũru ède, nwọn si nyìn Ọlọrun logo. Nigbana ni Peteru dahùn wipe,
46 For they heard them speak with tongues, and magnify God. Then answered Peter,
47 Ẹnikẹni ha le ṣòfin omi, ki a má baptisi awọn wọnyi, ti nwọn gbà Ẹmí Mimọ́ bi awa?
47 Can any man forbid water, that these should not be baptized, which have received the Holy Ghost as well as we?
48 O si paṣẹ ki a baptisi wọn li orukọ Jesu Kristi. Nigbana ni nwọn bẹ̀ ẹ ki o duro ni ijọ melokan.
48 And he commanded them to be baptized in the name of the Lord. Then prayed they him to tarry certain days.